Monday, 27 February 2017

Mase Padanu ANFANI TI ON KOJALO

          Opolopo ni awon anfani ti o ma n wa si odo wa ni opolopo igba, sugbon ti ako ni dawon mo gege bi anfani ti Olorun ti seto fun wa.
          Anfani lee wa gege bi ise, Owo, ebun, Imoran tabi gege bi iruni soke ati beebe lo. Lati wa ni ipo ase je anfani. Lati je Oba ilu je anfani. Ju gbogbo re lo, ti a ko ba kiyesi ara, anfani le bo sonu mo eniyan lowo gege bi omo oninakuna se padanu anfani tire ti oni ninu ile baba re. Aare orile ede, oba ilu le padanu anfani won ti won ba siwa hu. Anfani lee bo sonu ti eniyan ba jafara tabi ti ko ba ni afojusun.
          Ninu iwe Matthew 20:29-34, ari itan awon afoju meji ti won lo anfani ti o wa si oju ona won ti oju won sila. Awon afoju meji yi le ti gbo nipa Jesu ati awon ise iyanu ti o ti se ni awon ilu ti o yi won ka.
          Sugbon ti won ko ni anfani ati ore ofe lati baa pade nitoripe won wa ni ipo efoju. Oju kan na ni won nwa ti won Joko si titi ti won yo fi mu won pada lo sile ni asale. Ohun ti won ba fun won ni won man nje .
          Sugbon ni ojo kan, Jesu nkoja lo, ti awon eniyan sin kigbe nipa jesu. Ariwo na nposi eyi ti o tumo si wipe Jesu Kristi wa nitosi. Eyi tumosi anfani ti on kojalo. Awon afoju meji yi wa ni bi ti won man joko si won nduro de awon ti yio wa lati wa fun won ni ore. Sugbon ni kete ti won gbo ariwo nipa bibo jesu, ara won ko bale mo, won mo daju wipe anfani kan ni on koja lo yii ati wipe ti.awon bale padanu re, Ko si ona abayo fun won mo. Nipa idi eyi, won pinnu lokan ara won lati dide lati lo anfani ti on koja lo na  nipa kike tantan- Jesu! Jesu!! Jesu!!! Omo Dafidi sanu fun wa. Bi won se so eleyi kikan kikan beni won tubo wa gbogbo ona lati fi de ibiti Jesu wa, laifi ti awon ipenija, idiwo ati koto, gegele ti owa si oju ona won ni akoko yii Koda, won ko fi aye gba ewu gereye ti won wo lati di won lowo.
          Dipo eyi, seni won tubo n kigbe- "Jesu omo Dafidi, saanu fun wa." Awon ero tile kigbe lewon lori ni ete ati pawon lenu mo sugbon nseni won tubo nke tantan, Jesu omo Dafidi, saanu fun wa. 
          Nigbati Jesu gbo ohun won, o kigbe osi bi won wipe "Kini efe ki n se fun yin?"
          Oluwa, won so, a fe riran! Aanu won se Jesu Lojukana, Jesu wipe, "Igbagbo re mu o larada" Oju won si ya, won si tele Jesu.
          Nje elese ni o bi, agan, nje odi ni o bi? Afoju, Aro, tabi eniti emi okukun  nponloju. Ohun.ti onilo lati se ni lati dide  wuya lati koju anfani ti o wa ni arowoto re gege bi awon okunrin afoju na ti se eyi, Jesu , anfani ti onkoja lo yio siju anu wo o.
          Anfani na wa nitosire, ti onkoja lo ni enu ona re, Anfani na ni Jesu ti on koja lo niwaju ile re. O n gba awon eniyan ti won npariwo re, awon eniyan  nsoro re , won nwasu re, nwon gbadura pelu oruko re.
          Kini owa de ti ofini lo anfani yi loni gege bi awon afoju meji yi ti se? O lee kepe Jesu fun iwosan gegebi awon afoju meji ni ti se ati bi Zakeu ti se gege. O tiraka latiri Jesu. Ki wase ohun nikan, igbala wa wo ile re wa, Iwosan, itusile, Aluyo, Ominira kuro labe ijegaba emi okunkun ati paapa julo igbala lee je tire ti oba lo amfani na ti onkoja lo ti oba tiraka lati ri Jesu.
          "Iwo yio mo otito, otito ti agbodo mo lati di ominira". Ohun nikan ni ole so ni di ominira.
            Nitorina, rin ninu re, gbe ninu re, Maa sin ki otito na tii se abuda ti o ro mo Olorun omo, Olorun emimo. yio ti ipase nkan wonyi fi idimule ninu aye re, nigbana ni ato le di ominira ni tooto."
                                  Nje ose tan lati si ilekun okan re fun Jesu? On duro ni enu ona okan re. ti o ba si ilekun fun loni, ola le peju. Jeki igbe na dun si eti re bi o ti se dun si eti Sakeu ninu iwe luku 19:9.
          Ti o ba se tan lati fi aiye re fun jesu, jowo gba adura igbagbo yi ki o si gba gbo wipe o ti de ni igbala.
          Olorun mi, mo mo wipe mi ole gba ara mila. Mo jewo gbogbo ese mi, mo si fi igbagbo mi si inu eje ti o ta sile  fun mi lori igi agbelebu lati san gbogbo igbese mi. Mo wa gbekele o wipe omu mi lo si orun.
                             Mo dupe lowo re pe o gba mi, Amin.